E wole f’oba Ologo julo

 


1. E wole f’oba, Ologo julo
E korin ipa ati ife Re
Alabo wa ni at’eni igbani
O ngbe ‘nu ogo, Eleru ni iyin


2. E so t’ipa Re, e so t’ore Re
‘mole l’aso Re, gobi Re orun
Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je.
Ipa ona Re ni a ko si le mo


3. Aye yi pelu ekun ‘yanu Re
Olorun agbara Re l’oda won
O fi id ire mule, ko si le yi
O si f’okun se aso igunwa Re.


4. Enu ha le so ti itoju Re ?
Ninu afefe, ninu imole
Itoju Re wa nin’odo ti o nsan
O si wa ninu iri ati ojo


5. Awa erupe aw’a lailera
‘wo l’a gbekele, o ki o da ni
Anu Re rorun, o si le de opin
Eleda, Alabo, Olugbala wa


6. ‘Wo Alagbara Onife julo
B’awon angeli ti nyin O loke
Be l’awa eda Re, niwon t’a le se
A o ma juba Re, a o ma yin O. Amin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *