E Maa Tesiwaju Kristiani Ologun

 


E maa te siwaju, Kristian ologun,
Maa tejumo mo Jesu t’o mbe niwaju
Kristi Oluwa wa ni Balogun wa,
Wo! asia Re wa niwaju ogun;


Ref
E ma te siwaju, Kristian ologun,
Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju.


Bi egbe ogun nla, n’Ijo Olorun,
Ara, a nrin l’ona t’awon mimo nrin;
A ko ya wa n’ipa, egbe kan ni wa,
Okan ni ireti ni Ekan ni ife.


Ite at’ ijoba wonyi le parun,
Sugbon Ijo Jesu y’o wa titi lai,
Orun apadi ko le bori’Ijo yia,
A n’ileri Kristi, eyi ko le ye.


E ma ba ni kalo, enyin eniyan;
D’ ohun yin po mo wa, l’ orin isegun,
Ogo, iyin, ola fun Kristi Oba,
Eyi ni y’o ma je orin wa titi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *