Sa Gbekele

 


‘Gbat a b’Oluwa rin N’nu mole oro re
Ona wa yio ti ni mole to
‘Gbata a ba nse ‘fe Re On yio ma ba wa gbe
Ati awon t’o gbeke won le


Egbe
Sa gbeke le, Ona miran ko si
Lati l’ayo n’nu Jesu, Ju pe k’a gbekele


Ko s’ohun t’o le de L’oke tabi ni’le
T’o le ko agbara Re l’oju
Iyemeji, eru, ibanuje, ekun
Ko le duro bi a gbekele


Ko si wahala mo Tabi ibanuje
O ti san gbogbo gbese’ wonyi
Ko si arokan mo, Tabi ifa juro
Sugbon bukun, b’a ba gbeke le


Ako le f’enu so Bi ‘fe Re ti po to
Titi a o f’ara wa rubo
Anu ti o nfihan At’ayo t’o nfun ni
Je ti awon ti o gbeke le


Nibi ‘pade ayo ka joko ni ese Re.
Tabi kajo rin ni ona Re.
Oun to so la o se, ibi to wu la o lo;
Kosi beru, ka sa gbekele.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *