Ojonla Lojo Na

 


Ojo nla l’ojo ti mo yan Olugbala l’ Olorun mi
O ye ki okan mi ma yo K’o si ro ihin na ka le.


Refrain Ojo nla l’ojo na, Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki nma gbadura Ki nma sora, ki nsi ma yo
Ojo nla l’ojo na, Ti Jesu we ese mi nu.


Eje mimo yi ni mo je F’ enit’ o ye lati feran
Je k’orin didun kun ‘le Re Nigba mo ba nlo sin nibe.


Ise igbala pari na Mo di t’Oluwa mi loni
On l’o pe mi ti mo si je Mo f’ ayo jipe mimo na.


Simi, aiduro okan mi Simi le Jesu Oluwa
Tani je wipe aiye dun Ju odo awon Angeli?


Enyin orun, gbo eje mi Eje mi ni ojojumo
Em’ o ma so dotun titi Jesu y’o fi mu mi re ‘le.

Leave a Reply

Your email address will not be published.