Mo gb’ohun Jesu t’o wipe

 


1. Mo gb’ohun Jesu t’o wipe,
Wa simi lodo Mi;
‘Wo alare, gbe ori re
Le okan-aya Mi!
N’nu are on ibinuje,
Ni mo to Jesu wa;
Lodo Re, mo r’ibi-’simi,
On si mu ‘nu mi dun.


2. Mo gb’ohun Jesu to wipe,
Iwo ti ongbe ngbe,
Uno f’omi ‘ye fun o l’ofe
Bere, mu, ko si ye!
Mo to Jesu wa, mo si mu
N’nu omi iye na;
Okan mi tutu, o soji,
Mo d’alaye n’nu Re


3. Mo gb’ohun Jesu to wipe,
Mole aye l’Emi;
Wo mi, orun re yo si la,
Ojo re yo dara
Mo wa Jesu n’nu Re mo ri
‘Rawo at’ Orun mi;
N’nu’ mole Re l’emi yo rin
Tit’ ajo mi yo pin.
Amin

Leave a Reply

Your email address will not be published.