Ko Su Wa Lati Ma Ko Orin ti

 


1.Ko su wa lati ma ko orin ti igbani Ogo f’olorun Aleluya
A le fi igbagbo korin na s’oke kikan Ogo f’olorun, Aleluya!


Refrain:
Omo olorun ni eto lati ma bu s’ayo Pe ona yi nye wa si,
Okan wa ns’aferi Re Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo,
Ogo f’olorun, Aleluya!


2. Awa mbe n’nu ibu ife t’o ra wa pada, ogo f’olorun Aleluya!
Awa y’o fi iye goke lo s’oke orun Ogo f’olorun, Aleluya!


3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko, ogo f’olorun Aleluya!
Nibiti a ori Oba ogo n’nu ewa Re Ogo f’olorun, Aleluya!


4. Nibe ao korin titun t’anu t’o da wa nde Ogo f’olorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin ‚yin ti Krist; Ogo f’olorun, Aleluya

Leave a Reply

Your email address will not be published.