Jesu yo joba ni gbogbo

 


1. Jesu yo joba ni gbogbo
Ibit’ aba le ri orun:
‘Joba Re yo tan kakiri,
‘Joba Re ki o nipekun.


2. On li ao ma gbadura si,
Awon oba yo pe l’Oba;
Oruko Re b’orun didun
Y’o ba ebo oro g’oke.


3. Gbogbo oniruru ede,
Yo fi ‘fe Re korin didun;
Awon omode yo jewo,
Pe ‘bukun won t’odo Re wa.


4. ‘Bukun po nibi t’On joba,
A tu awon onde sile,
Awon alare ri ‘simi,
Alaini si ri ‘bukun gba.


5. Ki gbogbo eda ko dide,
Ki won f’ola fun Oba wa;
K’angel’ tun wa t’awon t’orin
Ki gbogb’ aye jumo gberin.
Amin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *