Jesu boluso ma sin wa

 


Jesu b’Oluso ma sin wa
A nfe ike Re pupo
F’ounje didara Re bo wa
Tun agbo Re se fun wa
Olugbala! Olugbala!
O rawa tire la se


Tirẹ ni wa fi wa s‘ore,
mase amona fun wa
Gba agbo Rẹ lowo eṣe,
wa wa gba ta ba sina
Olugbala! Olugbala!
gbọ ti wa, ‘gba tan Bebe


O se leri lati gba wa,
Pel’ ese at’aini wa:
O lanu lati fi wo wa
Ipa lati da wa nde
Olugbala! Olugbala!
ni kutu, Ka w’ado Re


Je ka tete w’ojure Re
Ka se’fe Re ni kutu
Oluwa at’Olugbala,
F’ ife Re kun aiya wa;
Olugbala! Olugbala!
O fewa Feran wa si.

Leave a Reply

Your email address will not be published.