E yo ninu Oluwa

 


Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ,
Ẹyin t’ọkan rẹ ṣe dede;
Ẹyin t’o ti Yan Oluwa,
Le ‘banujẹ at’aro lọ.


Refrain:
Ẹ yọ! Ẹ yọ!
Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ!
Ẹ yọ! Ẹ yọ
Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ!


Ẹ yọ tori On l’ Oluwa,
L’ayé ati l’ọrun pẹlu;
Ọrọ Rẹ bor’ohun gbogbo,
O l’agbara lati gbala.


‘Gbat’ ẹ ba nja ija rere,
Ti ọta fẹrẹ bori yin;
Ogun Ọlọrun t’ẹ ko ri
Pọ jù awọn ọta yin lọ.


B’okunkun tilẹ yi ọ ka,
Pẹlu iṣudẹdẹ gbogbo
Maṣe jẹ k’ọkan rẹ danu,
Sa gbẹkẹl’Oluwa, d’opin.


Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ,
Ẹ kọrin iyin Rẹ kikan;
Fi duru ati ohun kọ
Aleluya l’ohun goro’.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *