Duro Duro fun Jesu

 

 


Duro, duro fun Jesu, Eyin om’ogun Krist:
Gbe asia Re soke A ko’gbodo fe ku;
Lati segun de ’segun Ni y’o to ogun Re;
Tit’ao segun gbogb’ota, Ti Krist yo j’Oluwa


Duro, duro fun Jesu F’eti s’ohun ipe
Jade lo s’oju ija L’oni ojo nla Re:
Enyin akin ti nja fun Larin ainiye ota,
Ni’n ewu en’ igboya Ekoju ija s’ota.


Duro, duro fun Jesu, Duro l’agbara Re
Ipa enia ko to Ma gbekele tire:
F’ihinrere hamora Ma sona, ma gbadura
B’ise tab’ ewu ba pe Ma se alai de ’be.


Duro, duro fun Jesu Ija na ki y’o pe;
Oni, ariwo ogun, Ola, orin ’segun,
Eni t’o ba si segun, Y’o gba ade iye
Y’o ma ba Oba Ogo Joba titi lailai Amin

 

Leave a Reply

Your email address will not be published.